1 Ẹ yin OLUWA!Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA.
2 Kí á yin orúkọ OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.
3 Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,kí á máa yin orúkọ OLUWA.
4 OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ.
5 Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run,
6 ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀láti wo ọ̀run ati ayé?
7 Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀,ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú,
8 láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè,àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀.
9 Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ,ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn.Ẹ máa yin OLUWA.