1 Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́;àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan.
2 Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀;ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ.
3 Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu,
4 àwọn tí ń wí pé,“Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun,àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?”
5 OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀,ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú,n óo dìde nisinsinyii,n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.”
6 Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA,ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀,tí a dà ninu iná nígbà meje.
7 Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelaekúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí.
8 Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri,níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi.