1 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.À ń kéde orúkọ rẹ,a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.
2 OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.
3 Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.
4 Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’
5 Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,ẹ má sì gbéraga.”
6 Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,tabi láti ìwọ̀ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.
7 Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.
8 Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.
9 Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu.
10 Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò;ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.