Orin Dafidi 45 BM

Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba

1 Èrò rere kan ń gbé mi lọ́kàn,mò ń kọ orin mi fún ọbaahọ́n mi dàbí gègé akọ̀wé tó mọṣẹ́.

2 Ìwọ ni o dára jùlọ láàrin àwọn ọkunrin;ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu rẹ,nítorí náà Ọlọrun ti bukun ọ títí ayé.

3 Sán idà rẹ mọ́ ìdí, ìwọ alágbára,ninu ògo ati ọlá ńlá rẹ.

4 Máa gun ẹṣin ìṣẹ́gun lọ ninu ọlá ńlá rẹ,máa jà fún òtítọ́ ati ẹ̀tọ́,kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ fún ọ ní ìṣẹ́gun ńlá.

5 Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn,àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ.

6 Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae.Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni.

7 O fẹ́ràn òdodo, o sì kórìíra ìwà ìkànítorí náà ni Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmì òróró yàn ọ́.Àmì òróró ayọ̀ ni ó fi gbé ọ gaju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ lọ.

8 Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari,láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.

9 Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ,ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.

10 Gbọ́, ìwọ ọmọbinrin, ronú kí o sì tẹ́tí sílẹ̀,gbàgbé àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ;

11 ẹwà rẹ yóo sì mú ọ wu ọba;òun ni oluwa rẹ, nítorí náà bu ọlá fún un.

12 Àwọn ará Tire yóo máa fi ẹ̀bùn wá ojurere rẹ,àní, àwọn eniyan tí wọ́n ní ọrọ̀ jùlọ.

13 Yóo máa wá ojurere rẹ,pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀.Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀,

14 ó wọ aṣọ aláràbarà, a mú un lọ sọ́dọ̀ ọba,pẹlu àwọn wundia ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọn ń sìn ín lọ.

15 Pẹlu ayọ̀ ati inú dídùn ni a fi ń mú wọn lọ,bí wọ́n ṣe ń wọ ààfin ọba.

16 Àwọn ọmọkunrin rẹ ni yóo rọ́pò àwọn baba rẹ;o óo fi wọ́n jọba káàkiri gbogbo ayé.

17 N óo mú kí á máa ki oríkì rẹ láti ìran dé ìran;nítorí náà àwọn eniyan yóo máa yìn ọ́ lae ati laelae.