Orin Dafidi 35 BM

Adura ìrànlọ́wọ́

1 OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà!

2 Gbá asà ati apata mú,dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́!

3 Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi!Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi.

4 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi,kí wọn ó tẹ́!Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú,kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn!

5 Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́,kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ!

6 Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀,kí angẹli OLUWA máa lépa wọn!

7 Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí.

8 Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!

9 Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀.

10 N óo fi gbogbo ara wí pé,“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbáralọ́wọ́ ẹni tí ó lágbáratí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”

11 Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí.

12 Wọ́n fi ibi san oore fún mi,ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.

13 Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn,aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀;mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà;mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata,

14 bí ẹni pé mò ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀rẹ́ mi, tabi arakunrin mi;mò ń lọ káàkiri, bí ẹni tí ń pohùnréré ẹkún ìyá rẹ̀,mo doríkodò, mo sì ń ṣọ̀fọ̀.

15 Ṣugbọn nígbà tí èmi kọsẹ̀, wọ́n kó ara wọn jọ,wọ́n ń yọ̀,wọ́n kó tì mí;pàápàá jùlọ, àwọn àlejò tí n kò mọ̀ ríbẹ̀rẹ̀ sí purọ́ mọ́ mi léraléra.

16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn mi, wọ́n ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n sì ń wò mí bíi pé kí n kú.

Adura Ìdáláre

17 OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa wò mí níran?Yọ mí kúrò ninu ogun tí wọn gbé tì mí,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn kinniun!

18 Nígbà náà ni n óo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan;láàrin ọpọlọpọ eniyan ni n óo máa yìn ọ́.

19 Má jẹ́ kí àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí yọ̀ mí,má sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra mi wò mí ní ìwò ẹ̀sín.

20 Nítorí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ alaafia sí àwọn tí wọn ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọnàfi kí wọ́n máa pète oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn.

21 Wọ́n la ẹnu, wọ́n ń pariwo lé mi lórí,wọ́n ń wí pé, “Ìn hín ìn, a rí ọ, ojú wa ló ṣe!”

22 O ti rí i, OLUWA, má dákẹ́.OLUWA, má jìnnà sí mi.

23 Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi!

24 Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí!

25 Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”Má jẹ́ kí wọn wí pé,“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.”

26 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;kí ìdààmú bá wọn;bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi.

27 Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mimáa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,kí wọ́n máa wí títí ayé pé,“OLUWA tóbi,inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

28 Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru.