Orin Dafidi 25 BM

Adura fún ìtọ́sọ́nà ati Ààbò

1 OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí.

2 Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé,má jẹ́ kí ojú ó tì mí;má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí.

3 OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ;àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì.

4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA,kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.

5 Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi,nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi;ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo.

6 OLUWA, ranti àánú rẹ, ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,nítorí wọ́n ti wà ọjọ́ ti pẹ́.

7 Má ranti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti ṣẹ̀ ní ìgbà èwe mi,tabi ibi tí mo ti kọjá ààyè mi;ranti mi, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ati nítorí oore rẹ.

8 Olóore ati olódodo ni OLÚWA,nítorí náà ni ó ṣe ń fi ọ̀nà han àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

9 A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́,a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀.

10 Gbogbo ọ̀nà OLUWA ni ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́,fún àwọn tí ń pa majẹmu ati òfin rẹ̀ mọ́.

11 Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí,nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.

12 Ẹni tí ó bá bẹ̀rù OLUWAni OLUWA yóo kọ́ ní ọ̀nà tí yóo yàn.

13 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà.

14 Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.

15 OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n.

16 Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi;nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi.

17 Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò;kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.

18 Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi,kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.

19 Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní,ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi.

20 Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,nítorí ìwọ ni mo sá di.

21 Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

22 Ọlọrun, ra Israẹli pada,kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.