Jobu 6 BM

1 Jobu bá dáhùn pé,

2 “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi,tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n,

3 ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ.Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀.

4 Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,oró rẹ̀ sì mú mi.Ọlọrun kó ìpayà bá mi.

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa kétí ó bá rí koríko jẹ?Àbí mààlúù a máa dúntí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?

6 Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹláì fi iyọ̀ sí i?Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?

7 Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.

8 “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.

9 Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.

10 Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.

11 Agbára wo ni mo ní,tí mo fi lè tún máa wà láàyè?Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?

12 Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?

13 Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.

14 “Ẹni tí ó bá kọ̀tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.

15 Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrátí ó yára kún,tí ó sì tún yára gbẹ,

16 tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn,tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ,

17 ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́,bí ilẹ̀ bá ti gbóná,wọn a sì gbẹ.

18 Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmíyà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiriwọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀.

19 Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá,àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí.

20 Ìrètí wọn di òfonítorí wọ́n ní ìdánilójú.Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀,ṣugbọn òfo ni wọ́n bá.

21 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii.Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín.

22 Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín?Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín,kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?

23 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?

24 “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.

25 Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára,ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí.

26 Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni?Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí?

27 Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn,ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára,nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín.

29 Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀,kí ẹ má baà ṣẹ̀.Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi.

30 Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni?Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?