Jobu 31 BM

1 “Mo ti bá ojú mi dá majẹmu;n óo ṣe wá máa wo wundia?

2 Kí ni yóo jẹ́ ìpín mi lọ́dọ̀ Ọlọrun lókè?Kí ni ogún mi lọ́dọ̀ Olodumare?

3 Ṣebí jamba a máa bá àwọn alaiṣododo,àjálù a sì máa dé bá àwọn oníṣẹ́-ẹ̀ṣẹ̀.

4 Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi,ó sì mọ ìrìn mi.

5 Bí mo bá rìn ní ọ̀nà aiṣododo,tí mo sì yára láti sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,

6 (kí Ọlọrun gbé mi ka orí ìwọ̀n tòótọ́,yóo sì rí i pé olóòótọ́ ni mí!)

7 Bí mo bá ti yí ẹsẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tààrà,tí mò ń ṣe ojúkòkòrò,tí ọwọ́ mi kò sì mọ́,

8 jẹ́ kí ẹlòmíràn kórè oko mi,kí o sì fa ohun ọ̀gbìn mi tu.

9 “Bí ọkàn mi bá fà sí obinrin olobinrin,tabi kí n máa pẹ́ kọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà aládùúgbò mi;

10 jẹ́ kí iyawo mi máa se oúnjẹ fún ẹlòmíràn,kí ẹlòmíràn sì máa bá a lòpọ̀.

11 Nítorí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jù,ẹ̀ṣẹ̀ tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún.

12 Iná ajónirun ni,tí yóo run gbogbo ohun ìní mi kanlẹ̀.

13 “Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọniranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi,nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí,

14 báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun?Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi?

15 Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.

16 “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,

17 tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ

18 (láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un,tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀);

19 bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,nítorí àìrí aṣọ bora,tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,

20 kí ó sì súre fún mi,nítorí pé ara rẹ̀ móorupẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun,

21 bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba,nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́,

22 jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi,kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀.

23 Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí,nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò.

24 “Bí mo bá gbójú lé wúrà,tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi,

25 bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ,tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní.

26 Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn,tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀:

27 tí ọkàn mi fà sí wọn;tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn.

28 Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún;nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run.

29 “Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi,tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i.

30 (N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú);

31 bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé,‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’

32 (Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba,nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò);

33 bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,

34 nítorí pé mò ń bẹ̀rù ọpọlọpọ eniyan,ẹ̀gàn ìdílé sì ń dẹ́rùbà mí,tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi dákẹ́, tí n kò sì jáde síta.

35 Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi!(Mo ti tọwọ́ bọ̀wé,kí Olodumare dá mi lóhùn!)Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí!

36 Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi,ǹ bá fi dé orí bí adé;

37 ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun,ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè.

38 “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí,tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún;

39 tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀,tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín,

40 kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà,kí koríko hù dípò ọkà baali.”Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín.