Jobu 14 BM

1 “Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,ó sì kún fún ìpọ́njú.

2 Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù.Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́.

3 Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ,tí ò ń bá ṣe ẹjọ́?

4 Ta ló lè mú ohun mímọ́ jádeláti inú ohun tí kò mọ́?Kò sí ẹni náà.

5 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un,tí o mọ iye oṣù rẹ̀,tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá.

6 Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi,kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe.

7 “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé,yóo tún pada rúwé,ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ.

8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀,tí kùkùté rẹ̀ sì kú,

9 bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ,yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.

10 Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì,bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí.

11 Bí adágún omi tíí gbẹ,ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ,

12 bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn,tí kì í sìí jí mọ́,títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí,tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.

13 Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì,kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀,ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.

14 Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.

15 O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16 Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.

17 O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.

18 “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.

19 Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta,tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ,bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo.

20 O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ,o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ.

21 Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀,a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i.

22 Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀,ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.”