Jobu 9 BM

1 Jobu dáhùn pé:

2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí,ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?

3 Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn,olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.

4 Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀,agbára rẹ̀ sì pọ̀.Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?

5 Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀;tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.

6 Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀,àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.

7 Ó pàṣẹ fún oòrùn,oòrùn kò sì yọ;ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;

8 òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ,tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.

9 Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run:Beari, Orioni, ati Pileiadesiati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù.

10 Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá,ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.

11 Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i,ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.

12 Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà,ta ló lè dá a dúró?Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’

13 “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró,yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.

14 Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́?Kí ni kí n sọ?

15 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn.Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú,lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.

16 Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́,tí ó sì dá mi lóhùn,sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.

17 Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀,ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;

18 kò ní jẹ́ kí n mí,ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.

19 Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni,agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ!Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́,ta ló lè pè é lẹ́jọ́?

20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi,sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí;bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀,sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.

21 N kò lẹ́bi,sibẹ n kò ka ara mi kún,ayé sú mi.

22 Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀,nítorí náà ni mo fi wí pé,ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun.

23 Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀,tí ó já sí ikú òjijì,a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.

24 A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú.Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun,ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?

25 “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete,kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.

26 Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi,bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.

27 Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi,kí n sì tújúká;kí n má ronú mọ́;

28 ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí,nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.

29 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi,kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún?

30 Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀,kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́,

31 sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí.Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.

32 Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi,tí mo fi lè fún un lésì,tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́.

33 Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji,tí ó lè dá wa lẹ́kun.

34 Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀,kí ó má nà mí mọ́!Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́!

35 Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù,nítorí mo mọ inú ara mi.