Jobu 34 BM

1 Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,

2 “Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n,ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀,

3 nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò,bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò

4 Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́,kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa.

5 Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi,ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre.

6 Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn.

7 “Ta ló dàbí Jobu,tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo,

8 tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn?

9 Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan,ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’

10 “Nítorí náà ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin olóye,Ọlọrun kì í ṣe ibi,Olodumare kì í ṣe ohun tí kò tọ́.

11 Nítorí a máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ati gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.

12 Nítòótọ́, Ọlọrun kì í ṣe ibi,bẹ́ẹ̀ ni Olodumare kì í dájọ́ èké.

13 Ta ló fi í ṣe alákòóso ayé,ta ló sì fi jẹ olórí gbogbo ayé?

14 Bí Ọlọrun bá gba ẹ̀mí rẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,tí ó sì gba èémí rẹ̀ pada sọ́dọ̀,

15 gbogbo eniyan ni yóo ṣègbé,tí wọn yóo sì pada di erùpẹ̀.

16 “Bí ẹ bá ní òye, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ.

17 Ǹjẹ́ ẹni tí ó kórìíra ìdájọ́ ẹ̀tọ́ lè jẹ́ olórí?Àbí ẹ lè dá olódodo ati alágbára lẹ́bi?

18 Ẹni tí ó tó pe ọba ní eniyan lásán,tí ó tó pe ìjòyè ní ẹni ibi;

19 ẹni tí kì í ṣe ojuṣaaju fún àwọn ìjòyè,tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju talaka lọ,nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.

20 Wọn á kú ikú òjijì, ní ọ̀gànjọ́ òru;á mi gbogbo eniyan jìgìjìgì, wọn a sì kú.Ikú á mú àwọn alágbára lọ láì jẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn wọ́n.

21 Nítorí pé ojú rẹ̀ tó gbogbo ọ̀nà tí eniyan ń tọ̀,ó sì rí gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ wọn.

22 Kò sí ibi òkùnkùn biribiri kankan,tí àwọn eniyan burúkú lè fi ara pamọ́ sí.

23 Nítorí Ọlọrun kò nílò láti yan àkókò kan fún ẹnikẹ́ni,láti wá siwaju rẹ̀ fún ìdájọ́.

24 Á pa àwọn alágbára run láìṣe ìwádìí wọn,á sì fi àwọn ẹlòmíràn dípò wọn.

25 Nítorí pé ó mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn,á bì wọ́n ṣubú lóru, wọn á sì parun.

26 Á máa jẹ wọ́n níyà ní gbangba,nítorí ìwà ibi wọn.

27 Nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé e,wọn kò náání ọ̀nà rẹ̀ kankan,

28 wọ́n ń jẹ́ kí àwọn talaka máa kígbe sí Ọlọrun,a sì máa gbọ́ igbe àwọn tí a ni lára.

29 “Bí Ọlọrun bá dákẹ́,ta ló lè bá a wí?Nígbà tí ó bá fi ojú pamọ́,orílẹ̀-èdè tabi eniyan wo ló lè rí i?

30 Kí ẹni ibi má baà lè ṣe àkóso,kí ó má baà kó àwọn eniyan sinu ìgbèkùn.

31 “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì sọ fún Ọlọrun pé,‘Mo ti jìyà rí, n kò sì ní gbẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

32 Kọ́ mi ní ohun tí n kò rí,bí mo bá ti ṣẹ̀ rí, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́?’

33 Ṣé yóo san ẹ̀san fún ọ lọ́nà tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn,nítorí pé o kọ̀ ọ́?Nítorí ìwọ ni o gbọdọ̀ yan ohun tí ó bá wù ọ́, kì í ṣe èmi,nítorí náà, sọ èrò ọkàn rẹ fún wa.

34 Àwọn tí wọ́n lóye yóo sọ fún mi,àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọn ń gbọ́ mi yóo sọ pẹlu pé,

35 ‘Jobu ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,ó ń sọ̀rọ̀ láìní òye tí ó jinlẹ̀.’

36 À bá lè gbé ọ̀rọ̀ Jobu yẹ̀wò títí dé òpin,nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí eniyan burúkú.

37 Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá;ó ń pàtẹ́wọ́ ẹlẹ́yà láàrin wa,ó sì ń kẹ́gàn Ọlọrun.”