Jobu 38 BM

OLUWA dá Jobu Lóhùn

1 Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle.

2 Ó bi í pé,“Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn,tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀?

3 Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn.

4 Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.

5 Ta ló ṣe ìdíwọ̀n rẹ̀–ṣebí o mọ̀ ọ́n, dá mi lóhùn!Àbí ta ló ta okùn ìwọ̀n sórí rẹ̀?

6 Orí kí ni a gbé ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé,àbí ta ló fi òkúta igun rẹ̀ sọlẹ̀;

7 tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin,tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?

8 Ta ló tìlẹ̀kùn mọ́ òkun,nígbà tí ó ń ru jáde,

9 tí mo fi awọsanma ṣe ẹ̀wù rẹ̀,tí òkùnkùn biribiri sì jẹ́ ọ̀já ìgbànú rẹ̀,

10 tí mo sì pa ààlà fún un,tí mo sé ìlẹ̀kùn mọ́ ọn,

11 tí mo wí pé, ‘Dúró níhìn-ín, o kò gbọdọ̀ kọjá ibẹ̀,ibí ni ìgbì líle rẹ ti gbọdọ̀ dáwọ́ dúró?’

12 Jobu, láti ọjọ́ tí o ti dé ayé,ǹjẹ́ o ti pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mọ́ rí,tabi pé kí àfẹ̀mọ́jú mọ́ àkókò rẹ̀,

13 kí ìmọ́lẹ̀ lè tàn sí gbogbo ayé,kí ó sì lè gbọn àwọn ẹni ibi dànù,kúrò ní ibi ìsápamọ́sí wọn?

14 A ti yí ayé pada bí amọ̀ tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀,ati bí aṣọ tí a pa láró.

15 A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,a sì ká wọn lápá kò.

16 “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?

17 Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?

18 Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

19 “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,

20 tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?

21 Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,o sá ti dàgbà!

22 “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí,tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí,

23 àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu,fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà?

24 Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá,tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé?

25 “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò,ati fún ààrá,

26 láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan,ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni?

27 Láti tẹ́ aṣálẹ̀ lọ́rùn,ati láti mú kí ilẹ̀ hu koríko?

28 Ṣé òjò ní baba; àbí, baba wo ló sì bí ìrì?

29 Ìyá wo ló bí yìnyín,inú ta ni òjò dídì sì ti jáde?

30 Ó sọ omi odò di líle bí òkúta,ojú ibú sì dì bíi yìnyín.

31 “Ṣé o lè fokùn so ìràwọ̀ Pileiadesi,tabi kí o tú okùn ìràwọ̀ Orioni?

32 Ṣé o lè darí àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀, ní àkókò wọn,tabi kí o ṣe atọ́nà ìràwọ̀ Beari ati àwọn ọmọ rẹ̀?

33 Ṣé o mọ àwọn òfin tí ó de ojú ọ̀run?Tabi o lè fìdí wọn múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

34 “Ǹjẹ́ o lè pàṣẹ fún ìkùukùu pé,kí ó rọ òjò lé ọ lórí?

35 Ṣé o lè pe mànàmáná pé kí ó wá kí o rán an níṣẹ́kí ó wá bá ọ kí ó wí pé, ‘Èmi nìyí?’

36 Ta ló fi ọgbọ́n sinu ìkùukùuati ìmọ̀ sinu ìrì?

37 Ta ló lè fi ọgbọ́n ká ìkùukùu,tabi tí ó lè tú omi inú ìkùukùu dà sílẹ̀,

38 nígbà tí ilẹ̀ bá gbẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí ó dì, tí ó sì le koko?

39 “Ṣé o lè wá oúnjẹ fún kinniun,tabi kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọ̀dọ́ kinniun lọ́rùn,

40 nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ ninu ihò wọn,tabi tí wọ́n ba ní ibùba wọn?

41 Ta ní ń wá oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò,nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá kígbe sí Ọlọrun,tí wọ́n sì ń káàkiri tí wọn ń wá oúnjẹ?