Jobu 16 BM

1 Jobu bá dáhùn pé,

2 “Èmi náà ti gbọ́ irú nǹkan wọnyi rí,ọlọ́rọ̀ ìtùnú kòbákùngbé ni gbogbo yín.

3 Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ yìí tilẹ̀ lópin?Àbí, kí ní ń fa gbogbo àríyànjiyàn yìí?

4 Bí ẹ bá wà ní ipò mi,èmi náà lè sọ̀rọ̀ bí ẹ tí ń sọ̀rọ̀ yìí,kí n da ọ̀rọ̀ bò yín,kí n sì máa mi orí si yín.

5 Mo lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fun yín lókun,kí ọ̀rọ̀ ìtùnú mi sì mú kí ara tù yín.

6 “Bí mo sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ kò mú kí ara tù mí,bí mo bá sì dákẹ́, ṣé dídákẹ́ lè tán ìrora mi?

7 Dájúdájú Ọlọrun ti dá mi lágara,ó ti sọ gbogbo ilé mi di ahoro.

8 Híhunjọ tí ara mi hunjọ, jẹ́ ẹ̀rí láti ta kò mí;rírù tí mo rù ta àbùkù mi,ó sì hàn lójú mi.

9 Ó ti fi ibinu fà mí ya,ó sì kórìíra mi;ó pa eyín keke sí mi;ọ̀tá mi sì ń fojú burúkú wò mí.

10 Àwọn eniyan ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,wọ́n ń gbá mi létí,wọ́n kó ara wọn jọ sí mi.

11 Ọlọrun fà mí lé eniyan burúkú lọ́wọ́,ó mú kí n ṣubú sí ọwọ́ àwọn ìkà.

12 Nígbà tí ó dára fún mi,ó fi ẹ̀yìn mi wọ́nlẹ̀,ó fún mi lọ́rùn, ó gbé mi ṣánlẹ̀,ó sì gbọ̀n mí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́;ó yàn mí sọjú bí àmì ìtafà sí.

13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká,ó la kíndìnrín mi láìṣàánú mi,ó sì tú òróòro mi jáde.

14 Ó ń gbógun tì mí nígbà gbogbo,ó pakuuru sí mi bí ọmọ ogun.

15 “Mo fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara,mo sùn gbalaja sinu erùpẹ̀.

16 Mo sọkún títí ojú mi fi pọ́n,omijé sì mú kí ojú mi ṣókùnkùn,

17 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ibi,adura mi sì mọ́.

18 “Ìwọ ilẹ̀, má ṣe bo ẹ̀jẹ̀ mi mọ́lẹ̀,má sì jẹ́ kí igbe mi já sí òfo.

19 Nisinsinyii, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ lọ́run,alágbàwí mi sì ń bẹ lókè.

20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,mo sì ń sọkún sí Ọlọrun,

21 ìbá ṣe pé ẹnìkan lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọrun,bí eniyan ti lè ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀ níwájú eniyan.

22 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí i,n óo lọ àjò àrèmabọ̀.