Jobu 28 BM

Ọ̀rọ̀ Ìyìn Nípa Ọgbọ́n

1 “Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka,ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà.

2 Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin,a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta.

3 Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀,a sì ṣe àwárí irin,ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri.

4 Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì,níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé,àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn,wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì.

5 Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde,ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po,ó gbóná janjan.

6 Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀,wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀.

7 Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o.

8 Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà,kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí.

9 “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ,á sì hú òkè ńlá tìdítìdí.

10 Á gbẹ́ ihò sinu àpáta,ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye.

11 Á dí orísun àwọn odò,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun,á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde.

12 Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n?Níbo sì ni ìmọ̀ wà?

13 “Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà;bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè.

14 Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’

15 Wúrà iyebíye kò lè rà á,fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀.

16 A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀,tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye.

17 Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ,a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀.

18 Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali,ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ.

19 A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia,tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á.

20 “Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá;níbo sì ni ìmọ̀ wà?

21 Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè,ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

22 Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé,‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’

23 “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀,òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀.

24 Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé,ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run.

25 Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi,

26 nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò,tí ó sì lànà fún mànàmáná.

27 Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde,ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.

28 Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé,‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n,kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”