Jobu 36 BM

1 Elihu tún tẹ̀síwájú ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní,

2 “Ní sùúrù fún mi díẹ̀, n óo ṣe àlàyé fún ọ,nítorí mo ní ohun kan tí mo fẹ́ gbẹnusọ fún Ọlọrun.

3 N óo gba ìmọ̀ mi láti ọ̀nà jíjìn,n óo sì fi júbà Ẹlẹ́dàá mi, tí ó ní ìmọ̀ òdodo.

4 Nítorí òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ mi;ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ péye ni èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.

5 “Ọlọrun lágbára, kì í kẹ́gàn ẹnikẹ́ni,agbára ati òye rẹ̀ pọ̀ gan-an.

6 Kì í jẹ́ kí eniyan burúkú ó wà láàyè,ṣugbọn a máa fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ẹ̀tọ́ rẹ̀.

7 Kìí mú ojú kúrò lára àwọn olódodo,ṣugbọn a máa gbé wọn sórí ìtẹ́ pẹlu àwọn ọba,á gbé wọn ga,á sì fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae.

8 Ṣugbọn bí a bá fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,tí ayé wọn kún fún ìpọ́njú,

9 a máa fi àṣìṣe wọn hàn wọ́n,ati ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga wọn.

10 Ó fún wọn ní etígbọ̀ọ́,ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

11 Bí wọ́n bá gbọ́ràn, tí wọ́n sì sìn ín,wọn yóo lo ọjọ́ ayé wọn pẹlu ìdẹ̀rùn,wọn yóo ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ninu ìgbádùn.

12 Ṣugbọn bí wọn kò bá gbọ́ràn,a óo fi idà pa wọ́n,wọn yóo sì kú láìní ìmọ̀.

13 “Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu,wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́,nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè.

14 Wọn á kú ikú ìtìjú,nígbà tí wọ́n wà ní èwe.

15 A máa lo ìpọ́njú àwọn tí à ń pọ́n lójú láti gbà wọ́n là,a sì máa lo ìdààmú wọn láti ṣí wọn létí.

16 A máa yọ ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú,bọ́ sinu ìdẹ̀ra níbi tí kò sí wahala,oúnjẹ tí a gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀ a sì jẹ́ kìkì àdídùn.

17 “Ṣugbọn, ìdájọ́ eniyan burúkú dé bá ọ,ọwọ́ ìdájọ́ ati òdodo sì ti tẹ̀ ọ́.

18 Ṣọ́ra kí ibinu má baà sọ ọ́ di ẹlẹ́yà,kí títóbi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì mú ọ ṣìnà.

19 Igbe ati agbára rẹ kò lè gbà ọ́ kúrò ninu ìpọ́njú.

20 Má máa dúró, kí o máa retí ọjọ́ alẹ́,nígbà tí à ń pa àwọn eniyan run.

21 Ṣọ́ra kí o má yipada sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀,tí ó wù ọ́ ju ìjìyà lọ.

22 “Wò ó, a gbé OLUWA ga ninu agbára rẹ̀;ta ni olùkọ́ tí ó dàbí rẹ̀?

23 Ta ló ń sọ ohun tí yóo ṣe fún un,tabi kí ó sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe yìí kò dára?’

24 Ranti láti gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,tí àwọn eniyan ń kọrin nípa rẹ̀.

25 Gbogbo eniyan ti rí i;àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè ń wò ó.

26 Wò ó, Ọlọrun tóbi lọ́ba, ju ìmọ̀ wa lọ,kò sí ẹni tí ó lè mọ ọjọ́ orí rẹ̀.

27 “Ó fa ìkán omi sókè láti inú ilẹ̀,ó sọ ìkùukùu di òjò,

28 ó sì rọ òjò sílẹ̀ láti ojú ọ̀runsórí ọmọ eniyan lọpọlọpọ.

29 Ta ló mọ bí ó ti tẹ́ ìkùukùu?Tabi bí ó ṣe ń sán ààrá láti inú àgọ́ rẹ̀?

30 Ó fi mànàmáná yí ara rẹ̀ ká,ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31 Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè;ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ lọpọlọpọ.

32 Ìkáwọ́ rẹ̀ ni mànàmáná wà,ó sì ń rán ààrá láti sán lu ohun tí ó bá fẹ́.

33 Ìró ààrá ń kéde bíbọ̀ rẹ̀,àwọn ẹran ọ̀sìn sì mọ̀ pé ó súnmọ́ tòsí.