4 Ǹjẹ́ ojú rẹ dàbí ti eniyan?Ǹjẹ́ a máa rí nǹkan bí eniyan ṣe rí i?
5 Ǹjẹ́ bí ọjọ́ ti eniyan ni ọjọ́ rẹ rí?Ǹjẹ́ ọdún rẹ rí bíi ti eniyan?
6 Tí o fi wá ń wádìí àṣìṣe mi,tí o sì ń tanná wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi,ati pé kò sí ẹnikẹ́nití ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.
8 Ọwọ́ rẹ ni o fi dá mi,ọwọ́ kan náà ni o sì tún fẹ́ fi pa mí run.
9 Ranti pé, amọ̀ ni o fi mọ mí,ṣé o tún fẹ́ sọ mí di erùpẹ̀ pada ni?
10 Ṣebí ìwọ ni o dà mí bí omi wàrà,tí o sì ṣù mí pọ̀ bíi wàrà sísè?