16 O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.
17 Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.
18 Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.
19 O óo sùn, láìsí ìdágìrì,ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ.
20 Àwọn ẹni ibi óo pòfo;gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálàni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú,ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”