14 Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun?Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo?
15 Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli,àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀.
16 Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyantí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin,tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi!
17 “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,n óo sọ ohun tí ojú mi rí,
18 (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,
19 àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).
20 Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.