17 “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,n óo sọ ohun tí ojú mi rí,
18 (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,
19 àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).
20 Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.
21 Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù,ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i.
22 Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn;ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun.
23 Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé,‘Níbo ló wà?’Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún!Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí.