24 Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á,wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun.
25 Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun,o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare,
26 ó ń ṣe oríkunkun sí i,ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà;
27 nítorí pé ó sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú rẹ̀ yíbò,ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ kìkì ọ̀rá.
28 Ó ń gbé ìlú tí ó ti di ahoro,ninu àwọn ilé tí eniyan kò gbọdọ̀ gbé,àwọn ilé tí yóo pada di òkítì àlàpà.
29 Kò ní ní ọrọ̀,ohun tí ó bá ní, kò ní pẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,òun alára kò sì ní fìdí múlẹ̀.
30 Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn,iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀,afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.