12 Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’
13 Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,
14 bí mo bá pe isà òkú ní baba,tí mo sì pe ìdin ní ìyá tabi arabinrin mi,
15 níbo ni ìrètí mi wá wà?Ta ló lè rí ìrètí mi?
16 Ṣé yóo lọ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ni?Ṣé àwa mejeeji ni yóo jọ wọ inú erùpẹ̀ lọ?”