7 Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,gbogbo ẹ̀yà ara mi dàbí òjìji.
8 Èyí ya àwọn olódodo lẹ́nu,aláìlẹ́bi sì dojú kọ ẹni tí kò mọ Ọlọrun.
9 Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.
10 Ṣugbọn ní tiyín, bí ẹ tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ,n kò ní ka ẹnikẹ́ni kún ọlọ́gbọ́n láàrin yín.
11 “Ọjọ́ ayé mi ti dópin, èrò ọkàn mi ti dàrú,àwọn ohun tí ọkàn mi ń fẹ́ sì ti di asán.
12 Wọ́n sọ òru di ọ̀sán,wọ́n ń sọ pé, ‘Ìmọ́lẹ̀ kò jìnnà sí òkùnkùn.’
13 Bí mo bá ní ìrètí pé ibojì yóo jẹ́ ilé mi,tí mo tẹ́ ibùsùn mi sinu òkùnkùn,