1 Bilidadi ará Ṣuha bá tún dáhùn pé,
2 “Ìgbàwo ni o óo sinmi ẹjọ́ tí ò ń tò yìí?Ohun tí a tí ń bá ọ sọ ni kí o gbé yẹ̀wò,kí á lè sọ èyí tí a tún fẹ́ sọ.
3 Kí ló dé tí o fi kà wá sí ẹranko,tí a di òmùgọ̀ lójú rẹ?
4 Ìwọ tí o faraya nítorí inú ń bí ọ,ṣé kí á sá kúrò láyé nítorí rẹ ni,tabi kí á ṣí àwọn àpáta nípò pada?
5 “Nítòótọ́, a ti pa fìtílà ẹni ibi,ahọ́n iná rẹ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.