6 Inú àgọ́ rẹ̀ ṣókùnkùn,a sì ti pa àtùpà ìgbèrí rẹ̀.
7 Agbára rẹ̀ ti dín kù,ète rẹ̀ sì gbé e ṣubú.
8 Ó ti ẹsẹ̀ ara rẹ̀ bọ àwọ̀n,ó ń rìn lórí ọ̀fìn.
9 Tàkúté ti mú un ní gìgísẹ̀,ó ti kó sinu pańpẹ́.
10 A dẹ okùn sílẹ̀ fún un,a sì dẹ pańpẹ́ sí ojú ọ̀nà rẹ̀.
11 “Ìbẹ̀rù yí i ká,wọ́n ń lé e kiri.
12 Ebi pa agbára mọ́ ọn ninu,ìṣòro sì ti ṣetán láti gbé e ṣubú.