10 Ó ba ayé mi jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà,ó sì ti parí fún mi,ó fa ìrètí mi tu bí ẹni fa igi tu.
11 Ibinu rẹ̀ ń jó mi bí iná,ó kà mí kún ọ̀tá rẹ̀.
12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kó ara wọn jọ,wọ́n dó tì mí,wọ́n sì pa àgọ́ tiwọn yí àgọ́ mi ká.
13 “Ó mú kí àwọn arakunrin mi jìnnà sí mi,àwọn ojúlùmọ̀ mi sì di àjèjì sí mi.
14 Àwọn ìyekan mi ati àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ti já mi kulẹ̀.
15 Àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sí ilé mi ti gbàgbé mi.Àwọn iranṣẹbinrin mi kà mí kún àlejò,wọ́n ń wò mí bí àjèjì.
16 Mo pe iranṣẹ mi, ṣugbọn kò dáhùn,bíbẹ̀ ni mo níláti máa bẹ̀ ẹ́.