21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi,nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!
22 Ọlọrun ń lépa mi,ẹ̀yin náà sì tún ń lépa mi!Kí ló dé tí ẹran ara mi kò to yín?
23 “À bá lè kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀!Àní, kí á kọ ọ́ sinu ìwé!
24 Kí á fi kálàmú irin ati òjékọ ọ́ sórí àpáta, kí ó wà níbẹ̀ títí lae.
25 Ṣugbọn mo mọ̀ pé Olùdáǹdè mi ń bẹ láàyè,ati pé, níkẹyìn, yóo dìde dúró lórí ilẹ̀ yóo sì jẹ́rìí mi,
26 lẹ́yìn tí awọ ara mi bá ti díbàjẹ́,ṣugbọn ninu ara mi ni n óo rí Ọlọ́run.
27 Fúnra mi ni n óo rí i,ojú ara mi ni n óo sì fi rí i,kì í ṣe ti ẹlòmíràn.“Ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì ninu mi!