13 bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde,tí ó pa ẹnu mọ́,
14 sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú,ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.
15 Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde;Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.
16 Yóo mu oró ejò,ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á.
17 Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò.
18 Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.
19 Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀,ó sì ti pa wọ́n tì sí apákanó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.