20 Nítorí pé oníwọ̀ra ni,tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan,kò lè pa á mọ́ra.
21 Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.
22 Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23 Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,tí yóo sì dà lé e lórí.
24 Bí ó bá ti ń sá fún idà,bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.
25 Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26 Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.