22 Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23 Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,tí yóo sì dà lé e lórí.
24 Bí ó bá ti ń sá fún idà,bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.
25 Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26 Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.
27 Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn,ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.
28 Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ,àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù.