12 Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.
13 Wọn a máa gbé inú ọlá,wọn a sì máa kú ikú alaafia.
14 Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.
15 Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín?Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’
16 Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà,nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
17 “Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi?Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí?Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?
18 Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko,tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?