20 Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn,kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.
21 Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú,nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀.
22 Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀,nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga?
23 Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀,nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,
24 ara rẹ̀ ń dán fún sísanra,ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.
25 Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn,láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.
26 Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀,tí ìdin sì bò wọ́n.