23 Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀,nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,
24 ara rẹ̀ ń dán fún sísanra,ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.
25 Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn,láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.
26 Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀,tí ìdin sì bò wọ́n.
27 “Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín,mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.
28 Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà;níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’
29 Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò?Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé,