31 Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀,tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe.
32 Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́,àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.
33 Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì,àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀;kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀.
34 Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu?Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín,tó ju irọ́ lọ.”