6 Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi,ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.
7 Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè,tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?
8 Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọndi eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.
9 Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.
10 Àwọn mààlúù wọn ń gùn,wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.
11 Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.
12 Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.