1 Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,
2 “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun?Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún.
3 Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare,tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?
4 Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí,tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?
5 Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀;tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?
6 O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí,O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.