10 Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká,tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.
11 Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran,ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12 “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀runÓ ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ,bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!
13 Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?
14 Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká,tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran,ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run.
15 “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé;ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?
16 A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó,a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.