16 A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó,a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.
17 Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé,‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’
18 Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn–ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.
19 Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,
20 wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun,iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’
21 “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun,kí o sì wà ní alaafia;kí ó lè dára fún ọ.
22 Gba ìtọ́ni rẹ̀,kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn.