23 Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀,tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ,
24 bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀,tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò,
25 bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ,ati fadaka olówó iyebíye rẹ,
26 nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare,o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.
27 Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́,o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe,yóo ṣeéṣe fún ọ,ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.
29 Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀,a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.