27 Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́,o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe,yóo ṣeéṣe fún ọ,ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.
29 Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀,a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.
30 A máa gba àwọn aláìṣẹ̀,yóo sì gbà ọ́ là,nípa ìwà mímọ́ rẹ.”