3 Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare,tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé?
4 Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí,tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́?
5 Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀;tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin?
6 O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí,O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto.
7 O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu,o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.
8 Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀,ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.
9 O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo,o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.