7 O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu,o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ.
8 Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀,ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀.
9 O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo,o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá.
10 Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká,tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì.
11 Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran,ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12 “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀runÓ ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ,bí ó ti wù kí wọ́n ga tó!
13 Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri?