13 “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀,tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà.
14 Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde,kí ó lè pa talaka ati aláìní,a sì dàbí olè ní òru.
15 Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú,ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’;ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.
16 Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri,ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́,wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí,wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀.
17 Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn,ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.”
18 Sofari dáhùn pé,“O sọ wí pé,‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.
19 Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹbẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.