18 Sofari dáhùn pé,“O sọ wí pé,‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.
19 Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹbẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.
20 Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú,ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’
21 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ,wọn kò sì ṣe rere fún opó.
22 Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀;wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn.
23 Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́,ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn.
24 A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀,lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé,a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà.