2 “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò,láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn,wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn.
3 Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ,wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.
4 Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́.
5 “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri,bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀,wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀.
6 Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olókowọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà.
7 Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru,wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù.
8 Òjò a pa wọ́n lórí òkè,wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò.