7 Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru,wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù.
8 Òjò a pa wọ́n lórí òkè,wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò.
9 (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú,wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.)
10 Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀;ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù.
11 Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà,òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn.
12 Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro,àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́,ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn.
13 “A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀,tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà.