10 Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi,ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀.
11 Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì,wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀.
12 Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́,nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu.
13 Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́;ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò.
14 Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀,díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀!Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?”