2 “Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára?Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà?
3 Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n?Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n?
4 Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi?Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀?
5 “Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀.Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì.
6 Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun,bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin.
7 Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú,ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú.
8 Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn,sibẹ ìkùukùu kò fà ya.