19 A ti máa wọlé sùn pẹlu ọrọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún un mọ́.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ yóo ti fò lọ.
20 Ìwárìrì á bò ó mọ́lẹ̀ bí ìkún omi,ní alẹ́, ìjì líle á gbé e lọ.
21 Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn á fẹ́ ẹ sókè,á sì gbé e lọ,á gbá a kúrò ní ipò rẹ̀.
22 Á dìgbò lù ú láìṣàánú rẹ̀,á sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.
23 Ọlọrun á pàtẹ́wọ́ lé e lórí,á sì pòṣé sí i láti ibi tí ó wà.