13 Wọ́n dínà mọ́ mi,wọ́n dá kún wahala mi,kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.
14 Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé,wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.
15 Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi,wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́,ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.
16 “Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi,ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.
17 Ní òru, egungun ń ro mí,ìrora mi kò sì dínkù.
18 Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.
19 Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,mo dàbí eruku ati eérú.