17 Ní òru, egungun ń ro mí,ìrora mi kò sì dínkù.
18 Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.
19 Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,mo dàbí eruku ati eérú.
20 “Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.
21 O dojú ibinu kọ mí,o fi agbára rẹ bá mi jà.
22 O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-únláàrin ariwo ìjì líle.
23 Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.